Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 75

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.

75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
    a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
    àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.

Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
    Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
    Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
    Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
    Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
    ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
    tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
    Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
    ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
    àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.

Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
    Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
    Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Daniẹli 12

Ìgbà ìkẹyìn

12 (A)“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. (B)Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. (C)Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. (D)Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”

Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè. Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

(E)Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn. 10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

11 (F)“Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290). 12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ (1,335).

13 “Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”

Matiu 12:15-21

Ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn

15 (A)Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá. 16 Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n kí ó má ṣe fi òun hàn. 17 Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Isaiah sọ nípa rẹ̀ pé:

18 (B)“Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn.
    Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;
èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.
    Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí.
19 Òun kì yóò jà, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe;
    ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.
20 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́,
    àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa.
Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìṣẹ́gun.
21     Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò fi ìrètí wọn sí.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.