Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.
75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”
6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.
Ìbínú Olúwa sí Ninefe
2 Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san.
Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú
Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,
Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀
3 (A)Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára;
Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà.
Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì,
Ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
4 Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ;
Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ.
Baṣani àti Karmeli sì rọ,
Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.
5 Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀,
àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́,
ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀,
àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
6 Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀?
Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀?
Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná;
àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.
7 Rere ni Olúwa,
òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,
8 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá
ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin;
òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9 Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa?
Òun yóò fi òpin sí i,
ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì
10 Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú
wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn
a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ
11 Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá
tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa
ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.
12 Báyìí ni Olúwa wí:
“Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye,
Ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀,
nígbà tí òun ó bá kọjá.
Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójú mọ́.
13 Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ
èmi yóò já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.”
12 Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.
13 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”
Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”
Ìkórè ayé
14 (A)Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o “dàbí Ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀. 15 (B)Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.” 16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.
17 Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan. 18 Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.” 19 Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run. 20 (C)A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.