Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 86:11-17

11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
    èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
    kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
    èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
    ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.

14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
    àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
    wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
    Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
    fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
    kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
    kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
    ni ó ti tù mí nínú.

Isaiah 44:18-20

18 Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;
    a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;
    bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.
19 Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,
    kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye
láti sọ wí pé,
    “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;
Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,
    Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.
Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan
    nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?
    Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”
20 Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà;
    òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé
    “Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”

Matiu 7:15-20

Igi àti èso rẹ̀

15 (A)“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.