Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.
65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
2 Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
3 Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
ti tẹmpili mímọ́ rẹ.
5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun,
6 Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára
7 Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́
ríru ariwo omi wọn,
àti ìdágìrì àwọn ènìyàn
8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
ìwọ pè fún orin ayọ̀.
9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.
52 (A)Jí, jí, Ìwọ Sioni,
wọ ara rẹ ní agbára.
Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,
ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.
Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́
kì yóò wọ inú rẹ mọ́.
2 Gbọn eruku rẹ kúrò;
dìde sókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jerusalẹmu.
Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,
ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.
3 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;
“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,
láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”
4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.
“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀
lọ sí Ejibiti láti gbé;
láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.
5 (B)“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.
“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,
àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”
ni Olúwa wí.
“Àti ní ọjọọjọ́
orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.
6 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;
nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀
pé Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”
44 (A)Jesu sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi. 45 (B)Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi. 46 (C)Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.
47 (D)“Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là. 48 (E)Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 49 Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí. 50 Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀: nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.