Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:161-168

161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
    ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
    bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
    ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
    nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
    kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
    nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
    nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.

1 Ọba 21:1-16

Ọgbà àjàrà Naboti

21 Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Naboti ará Jesreeli sì ní ọgbà àjàrà kan ní Jesreeli, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Ahabu ọba Samaria. Ahabu sì wí fún Naboti pé, “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ, kí èmi kí ó fi ṣe ọgbà-ewébẹ̀, nítorí tí ó súnmọ́ tòsí ilé mi; Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀; tàbí bí ó bá sì dára ní ojú rẹ, èmi yóò fi iye owó rẹ̀ fún ọ.”

Ṣùgbọ́n Naboti wí fún Ahabu pé, “Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn baba mi fún ọ.”

Ahabu sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Naboti ará Jesreeli sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn baba mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun.

Jesebeli aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, Èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Nítorí tí mo wí fún Naboti ará Jesreeli pé, ‘Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, Èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó wí pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’ ”

Jesebeli aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Israẹli? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Naboti ará Jesreeli.”

Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Ahabu, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Naboti pẹ̀lú rẹ̀. Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé:

“Ẹ kéde àwẹ̀, kí ẹ sì fi Naboti sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn. 10 Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú síwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí sí i wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.”

11 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí wọ́n ń ṣe ará ìlú Naboti sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwé tí Jesebeli kọ ránṣẹ́ sí wọn. 12 Wọ́n sì kéde àwẹ̀, wọ́n sì fi Naboti sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn. 13 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí lòdì sí Naboti níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Naboti ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. 14 Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jesebeli wí pé: “A ti sọ Naboti ní òkúta, ó sì kú.”

15 Bí Jesebeli sì ti gbọ́ pé, a ti sọ Naboti ní Òkúta pa, ó sì wí fún Ahabu pé, “Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà Naboti, ará Jesreeli, tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láààyè mọ́, ó ti kú.” 16 Nígbà tí Ahabu sì gbọ́ pé Naboti ti kú, ó sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún ọgbà àjàrà Naboti.

1 Tẹsalonika 4:9-12

Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. 10 Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. 11 (A)Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín. 12 Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.