Revised Common Lectionary (Complementary)
7 Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
ìtìjú sì bo ojú mi.
8 Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;
àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;
9 (A)Nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,
àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.
10 Nígbà tí mo sọkún
tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà
èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;
11 Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,
àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.
12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,
mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.
13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni
ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,
ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà
Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,
dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.
14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,
Má ṣe jẹ́ kí n rì;
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,
kúrò nínú ibú omi.
15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì
kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.
16 Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”
13 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:
“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,
ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?
Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.
14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni
yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?
Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,
tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?
15 Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,
wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,
tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,
àti ọ̀nà wọn àtijọ́.
Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,
àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe
16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di
nǹkan ẹ̀gàn títí láé;
Gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,
wọn yóò sì mi orí wọn.
17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,
Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.
Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn
ní ọjọ́ àjálù wọn.”
Jesu bí arákùnrin rẹ̀
5 Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. 6 (A)Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:
“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,
tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
7 Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ;
ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,
ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:
8 Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”
Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ 9 Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.