Revised Common Lectionary (Complementary)
105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;
wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:
ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
8 (B)Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ
sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani
gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”
37 Ó mú Israẹli jáde
ti òun ti fàdákà àti wúrà,
nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.
39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.
42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde
pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀
44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,
wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Olúwa pàṣẹ fún Joṣua
1 Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose: 2 “Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli. 3 Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose. 4 Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. 5 (A)Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.
6 “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn. 7 Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ. 8 Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí. 9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
10 Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ 11 “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ”
Timotiu
3 (A)Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Ateni. 2 (B)Awa sì rán Timotiu, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Ọlọ́run nínú ìhìnrere Kristi, láti fi ẹsẹ yín múlẹ̀, àti láti tù yín nínú ní ti ìgbàgbọ́ yín. 3 (C)Láìsí àní àní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn tí ó gbàgbọ́, kí a má ba dààmú. 4 (D)Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò dé. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́. 5 (E)Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba á mọ́, mo sì ránṣẹ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ìgbàgbọ́ yín, kí olùdánwò nì má ba à dán an yín wò lọ́nàkọnà, kí làálàá wa sì jásí asán.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.