Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 100

Saamu. Fún ọpẹ́

100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
    Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
    ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
    àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

Eksodu 6:28-7:13

Aaroni di agbẹnusọ fún Mose

28 Nígbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ni Ejibiti, 29 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi ni Olúwa. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Farao ọba Ejibiti.”

30 Ṣùgbọ́n Mose sì wí ní iwájú Olúwa pé, “Níwọ́n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Farao yóò ṣe fi etí sí mi?”

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Wò ó, Èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Farao, Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ wòlíì (agbẹnusọ) rẹ. Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí Èmi ti pàṣẹ fún ọ, Aaroni arákùnrin rẹ yóò sísọ fún Farao kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀. (A)Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ni Ejibiti, síbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni Èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Ejibiti, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Àwọn ará Ejibiti yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Ejibiti, tí mo sì mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò níbẹ̀.”

Mose àti Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Mose jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún (80) Aaroni sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83) ni ìgbà tí wọ́n bá Farao sọ̀rọ̀.

Ọ̀pá Mose di ejò

Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni, “Ní ìgbà tí Farao bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Aaroni ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Farao,’ yóò sì di ejò.”

10 Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. 11 Farao sì pe àwọn amòye, àwọn oṣó àti àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mose àti Aaroni ṣe. 12 Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Ṣùgbọ́n ọ̀pá Aaroni gbé ọ̀pá tiwọn mì. 13 Síbẹ̀ ọkàn Farao sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

Marku 7:1-13

Mímọ́ àti àìmọ́

(A)Àwọn Farisi sì péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé, tí ó wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́. (Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́. (B)Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)

(C)Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun.”

(D)Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:

“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi
    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.
Ìsìn wọn jẹ́ lásán,
    ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’

Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.”

Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ. 10 (E)Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’ 11 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí ìyá rẹ̀ mọ́. 13 Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.