Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Hosea 5:15-6:6

15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi
    títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi
wọn yóò sì wá ojú mi
    nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

Àìronúpìwàdà Israẹli

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
    ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
    ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
    ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
    kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
    Yóò jáde;
Yóò tọ̀ wá wá bí òjò
    bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
    Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
    bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.
    Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi
    Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
(A)Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
    àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

Saamu 50:7-15

“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
    èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
Èmi kí yóò bá ọ wí
    nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
    ní ìgbà gbogbo.
Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
    tàbí kí o mú òbúkọ láti
inú agbo ẹran rẹ̀
10 Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
    àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
    àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
    nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
tí ó wa ní inú rẹ̀.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
    mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
    kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

Romu 4:13-25

13 (A)Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́. 14 (B)Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá jẹ ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára: 15 (C)Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú: ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀.

16 Nítorí náà ni ó ṣe gbé e ka orí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-ọ̀fẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú-ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Abrahamu, ẹni tí í ṣe baba gbogbo wa pátápátá, 17 (D)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ ṣe baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.

18 (E)Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” 19 (F)Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara: 20 Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run; 21 Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. 22 (G)Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un. 23 (H)Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan. 24 Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jesu Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́. 25 (I)Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.

Matiu 9:9-13

Ìpè Matiu

(A)Bí Jesu sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrin kan ti à ń pè ní Matiu, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Matiu sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

10 Ó sì ṣe, bí Jesu tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Matiu, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti “ẹlẹ́ṣẹ̀” wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 11 Nígbà tí àwọn Farisi sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èéṣe’ tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun pọ̀?”

12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. 13 Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ ohun ti èyí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Matiu 9:18-26

Ọmọbìnrin tó kú àti obìnrin onísun-ẹ̀jẹ̀

18 Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.” 19 Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

20 Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. 21 Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”

22 (A)Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà.

23 Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. 24 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde. 26 Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.