Revised Common Lectionary (Complementary)
7 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
8 Èmi kí yóò bá ọ wí
nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
ní ìgbà gbogbo.
9 Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
tàbí kí o mú òbúkọ láti
inú agbo ẹran rẹ̀
10 Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
tí ó wa ní inú rẹ̀.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?
14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni
Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀
tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.
Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,
kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un.
Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó
wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.
8 Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀
ó sì ti di aláìmọ́.
Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,
nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀;
ó kérora fúnrarẹ̀,
ó sì lọ kúrò.
9 Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀,
Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;
olùtùnú kò sì ṣí fún un.
“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,
nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”
10 Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé
gbogbo ìní rẹ;
o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè
tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—
àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀
láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.
11 Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora
bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;
wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ
láti mú wọn wà láààyè.
“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó,
nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
17 Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. 18 Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. 19 Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. 20 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. 21 Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. 22 (A)Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára: “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.