Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.
5 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,
kíyèsi àròyé mi.
2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
ọba mi àti Ọlọ́run mi,
nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
5 Àwọn agbéraga kò le è dúró
níwájú rẹ̀.
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
ni Olúwa yóò kórìíra.
7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi,
mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
9 (A)Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
ọkàn wọn kún fún ìparun.
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
Tan ààbò rẹ sórí wọn,
àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;
ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.
Ìgbàlà fún àwọn mìíràn
56 Èyí ni ohun ti Olúwa sọ:
“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́
ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,
nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí
àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.
2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,
àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,
tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,
tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”
3 Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀
mọ́ Olúwa sọ wí pé,
“Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,
“Igi gbígbẹ lásán ni mí.”
4 Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí:
“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,
tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi
tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
5 fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀
ìrántí kan àti orúkọ kan
tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé
tí a kì yóò ké kúrò.
6 Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa
láti sìn ín,
láti fẹ́ orúkọ Olúwa
àti láti foríbalẹ̀ fún un
gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́
àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—
7 (A)àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,
èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.
Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,
ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;
nítorí a ó máa pe ilé mi ní
ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
8 Olúwa Olódùmarè sọ wí pé—
ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ:
“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn
yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”
Ìgbàgbọ́ obìnrin ará Kenaani
24 (A)Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri. 25 Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. 26 Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
27 Jesu sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
28 Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ èérún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì.”
29 “Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”
30 Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.