Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 24

Ti Dafidi. Saamu.

24 (A)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
    ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
    ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
    Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
(B)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
    ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
    tí kò sì búra èké.

Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
    àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
    tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
    Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
    Kí ọba ògo le è wọlé.
Ta ni ọba ògo náà?
    Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
    Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
    kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
    kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

Isaiah 60:8-16

“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru,
    gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?
Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;
    ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn,
    pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn,
fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    Ẹni Mímọ́ Israẹli,
    nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.

10 “Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ
    àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,
    ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.
11 (A)Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
    a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó
    ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá
tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní
    ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.
12 Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;
    pátápátá ni yóò sì dahoro.

13 “Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
    igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,
láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;
    àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.
14 (B)Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò
    wá foríbalẹ̀ fún ọ;
gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ
    wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa,
    Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,
Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé
    àti ayọ̀ àtìrandíran.
16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè
    a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,
    èmi ni Olùgbàlà rẹ,
    Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.

Luku 1:1-4

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàrín wa, (A)àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́. (B)Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ, (C)kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti kọ́ ọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.