Revised Common Lectionary (Complementary)
Orin fún ìgòkè.
123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
2 Kíyèsi, bí ojú àwọn
ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4 Ọkàn wa kún púpọ̀
fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
Ìdáhùn Bilidadi
25 Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé:
2 “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,
òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.
3 Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,
tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
4 Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?
5 Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,
àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,
6 kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,
àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”
Ìdáhùn Jobu
26 Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé:
2 Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,
báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?
3 Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,
tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?
4 Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?
5 “Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,
lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
6 Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,
ibi ìparun kò sí ní ibojì.
7 Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,
ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.
8 Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;
àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.
9 Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,
ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.
10 Ó fi ìdè yí omi Òkun ká,
títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
11 Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,
ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.
12 Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;
nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.
13 Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;
ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.
14 Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;
ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!
Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”
19 (A)Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. 20 (B)Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. 21 (C)Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. 22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: 23 (D)Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.
24 (E)“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè. 25 (F)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè. 26 Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; 27 Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn.
28 “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. 29 (G)Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.