Revised Common Lectionary (Complementary)
Orin fún ìgòkè.
123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
2 Kíyèsi, bí ojú àwọn
ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4 Ọkàn wa kún púpọ̀
fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
Jobu dá Sofari lóhùn
21 Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé:
17 “Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú?
Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn,
tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?
18 Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́,
àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.
19 Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’
Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.
20 Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀,
yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.
21 Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,
nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?
22 “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀?
Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.
23 Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀,
ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.
24 Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú,
egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.
25 Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀,
tí kò sì fi inú dídùn jẹun.
26 Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀,
kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.
27 “Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti
àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.
28 Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé,
àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’
29 Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà?
Ẹ̀yin kò mọ̀ ààmì wọn, pé
30 ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun.
A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.
31 Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú,
ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?
32 Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú,
a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.
33 Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn.
Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́
lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.
34 “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán,
bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”
1 (A)Alàgbà,
Sì àyànfẹ́ obìnrin ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú; 2 nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.
3 Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú wa nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.
4 Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pa àṣẹ fún wa. 5 (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtètèkọ́ṣe, pé kí àwa fẹ́ràn ara wa. 6 (C)Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.
7 (D)Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi. 8 Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà. 9 Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ. 10 Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú ààbọ̀. 11 Nítorí ẹni tí ó bá kí kú ààbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.
12 (E)Bí mo tilẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alábápín pẹ̀lú yín, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ lo ìwé ìkọ̀wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.
13 Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.