Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 32:1-7

Ti Dafidi. Maskili.

32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
    tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
    àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

Nígbà tí mo dákẹ́,
    egungun mi di gbígbó dànù
    nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
    àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
    ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
    ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
    ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
    wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

Isaiah 1:1-9

Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.

Ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè kan

Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!
    Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀:
“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,
    Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
Màlúù mọ olówó rẹ̀,
    kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,
ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀,
    òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”

Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,
    àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,
Ìran àwọn aṣebi,
    àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!
Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀
    wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli,
wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.

Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?
    Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?
Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,
    gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù.
Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín
    kò sí àlàáfíà rárá,
àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa
    àti ojú egbò,
    tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.

Orílẹ̀-èdè yín dahoro,
    a dáná sun àwọn ìlú yín,
oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run
    lójú ara yín náà,
ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí
    àwọn àjèjì borí rẹ̀.
Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,
gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí,
    àti bí ìlú tí a dó tì.
Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà,
a ò bá ti rí bí Sodomu,
    a ò bá sì ti dàbí Gomorra.

Johanu 8:39-47

39 Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!”

Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu 40 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run: Abrahamu kò ṣe èyí. 41 (A)Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”

Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà: a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”

Àwọn ọmọ èṣù

42 (B)Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43 Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 44 (C)Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45 Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 46 Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? 47 Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.