Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 84:1-7

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
    ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
    sí Ọlọ́run alààyè.
Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
    ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
    níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
    wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
    àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
    wọn sọ ọ́ di kànga
    àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
    títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

Jeremiah 9:17-26

17 Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:

“Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá;
    sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.
18 Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,
    kí wọn wá pohùnréré ẹkún
lé wa lórí títí ojú wa yóò
    fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa
19 A gbọ́ igbe ìpohùnréré
    ẹkún ní Sioni:
    ‘Àwa ti ṣègbé tó!
A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,
    nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”

20 Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́
    ọ̀rọ̀ Olúwa. Ṣí etí yín sí
ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrin
    yín ní ìpohùnréré
    ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.
21 Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé
    ó sì ti wọ odi alágbára wa
ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní
    àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
    kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.

22 Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú
    bí ààtàn ní oko gbangba
àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè
    láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”

23 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn
    nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára
nítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀
    nítorí ọrọ̀ rẹ̀.
24 (A)Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń
    ṣògo nípa èyí nì wí pé
òun ní òye, òun sì mọ̀ mí
    wí pé, èmi ni Olúwa tí ń
ṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodo
    ní ayé nínú èyí ni mo ní
inú dídùn sí,”
    Olúwa wí.

25 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan. 26 Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”

2 Timotiu 3:10-15

Ọ̀rọ̀ ìyànjú Paulu sí Timotiu

10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 11 (A)Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.