Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
2 Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
sí Ọlọ́run alààyè.
3 Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
5 Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6 Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
wọn sọ ọ́ di kànga
àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
9 Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi
kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!
Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru
nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.
2 Háà, èmi ìbá ní ni aginjù
ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò,
kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀
kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:
nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà
àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.
3 Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀
bí ọfà láti fi pa irọ́;
kì í ṣe nípa òtítọ́
ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.
Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;
wọn kò sì náání mi,
ní Olúwa wí.
4 Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;
má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.
Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,
oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.
5 Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni
tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn
láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn
di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀
6 Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn
wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú
ẹ̀tàn wọn,
ni Olúwa wí.
7 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé
kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?
8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró
ó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálùkù sì ń
fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí
aládùúgbò rẹ̀; ní inú
ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.
9 Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara
mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”
10 Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré
ẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkún
ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì.
Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì
kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe
ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run
sì ti sálọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.
11 “Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì
àlàpà àti ihò àwọn ìkookò.
Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro
tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.”
12 Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?
13 Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. 14 Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn. 15 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé. 16 Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”
Ìwà àwọn ènìyàn ni ọjọ́ ìkẹyìn
3 Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. 2 Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. 3 Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, 4 oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. 5 Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
6 Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri 7 Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. 8 (A)Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. 9 Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.