Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 57

Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.

57 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
    títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
    sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
    yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
    Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.

Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
    mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
    ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
    kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
    a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

(A)Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
    ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
Jí, ìwọ ọkàn mi!
    Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
    Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.

Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
    èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
    òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.

11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
    kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

1 Samuẹli 25:2-22

Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli. Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nabali, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Abigaili; òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn; ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin; ẹni ìdílé Kalebu ni òun jẹ́.

Dafidi sì gbọ́ ní aginjù pé Nabali ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀. Dafidi sì rán ọmọkùnrin mẹ́wàá, Dafidi sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Karmeli, kí ẹ sì tọ Nabali lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi. Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!

“ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ́run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ Wò ó, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pa wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Karmeli. Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojúrere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àsè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àti fún Dafidi ọmọ rẹ.’ ”

Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nabali gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì sinmi.

10 Nabali sì dá àwọn ìránṣẹ́ Dafidi lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dafidi? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jese? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́ ni ń bẹ ni ìsinsin yìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀. 11 Ǹjẹ́ ki èmi o mú oúnjẹ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi sì fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”

12 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì padà, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 13 Dafidi sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idà rẹ́ mọ́ ìdí,” Olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ̀ mọ́ ìdí; àti Dafidi pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irínwó ọmọkùnrin si gòkè tọ Dafidi lẹ́yìn; igba si jókòó níbi ẹrù.

14 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin Nabali si wí fún Abigaili aya rẹ̀ pé, “Wo o, Dafidi rán oníṣẹ́ láti aginjù wá láti kí olúwa wa; ó sì kanra mọ́ wọn. 15 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà ṣe oore fún wa gidigidi, wọn kò ṣe wá ní ibi kan, ohunkóhun kò nù ni ọwọ́ wa ni gbogbo ọjọ́ ti àwa bá wọn rìn nígbà ti àwa ń bẹ lóko. 16 Odi ni wọ́n sá à jásí fún wa lọ́sàn án, àti lóru, ni gbogbo ọjọ́ ti a fi bá wọn gbé, tí a n bojútó àwọn àgùntàn. 17 Ǹjẹ́, rò ó wò, kí ìwọ sì mọ èyí ti ìwọ yóò ṣe; nítorí pé a ti gbèrò ibi sí olúwa wa, àti sí gbogbo ilé rẹ̀; òun sì jásí ọmọ Beliali tí a kò le sọ̀rọ̀ fún.”

18 Abigaili sì yára, ó sì mú igbá ìṣù àkàrà àti ìgò ọtí wáìnì méjì, àti àgùntàn márùn-ún, tí a ti ṣè, àti òṣùwọ̀n àgbàdo yíyan márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún ìdì àjàrà, àti igba àkàrà èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì dìwọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 19 Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Máa lọ níwájú mi; wò ó, èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín,” Ṣùgbọ́n òun kò wí fún Nabali baálé rẹ̀.

20 Bí o ti gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sì ń sọ̀kalẹ̀ sí ibi ìkọ̀kọ̀ òkè náà, wò ó, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ níwájú rẹ̀; òun sì wá pàdé wọn. 21 Dafidi sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyí tí i ṣe ti eléyìí ní aginjù, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni ó sì fi ibi san ìre fún mi yìí. 22 Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀tá Dafidi, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”

1 Kọrinti 6:1-11

Ìyànjú èdè-àìyedè àwọn onígbàgbọ́

(A)Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́? Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrín ara yín. Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí. Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ. Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́? Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.

(B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. (C)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ 10 tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. 11 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.