Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 121

Orin fún ìgòkè.

121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
    yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Gẹnẹsisi 32:3-21

Jakọbu sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Esau arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Seiri ní orílẹ̀-èdè Edomu. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Esau olúwa mi, Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani títí ó fi di àsìkò yìí Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”

Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irínwó (400) ọkùnrin.”

Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jakọbu fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ìbákasẹ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Esau bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.”

Nígbà náà ni Jakọbu gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Abrahamu baba mi, àti Ọlọ́run Isaaki baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, Èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’ 10 Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jordani yìí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì. 11 Jọ̀wọ́ Olúwa gbà mí lọ́wọ́ Esau arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. 12 (A)Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, ‘Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn Òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà.’ ”

13 Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún Esau arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀. 14 Igba ewúrẹ́ (200), ogún (20) òbúkọ, igba (200) àgùntàn, ogún (20) àgbò, 15 Ọgbọ̀n (30) abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì (40) abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá (10), ogún (20) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá (10). 16 Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrín ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkejì.”

17 Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Esau bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ, 18 Nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jakọbu ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Esau olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ”

19 Jakọbu sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Esau nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20 Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún un pé, ‘Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jakọbu ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Esau lójú pé bóyá inú Esau yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé. 21 Nítorí náà ẹ̀bùn Jakọbu ṣáájú rẹ̀ lọ, Jakọbu pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́.

Marku 10:46-52

46 (A)Wọ́n dé Jeriko, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jeriko, ọkùnrin afọ́jú kan, Bartimeu, ọmọ Timeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń ṣagbe.

Bartimeu afọ́jú gba ìwòsàn

47 (B)Nígbà tí Bartimeu gbọ́ pé Jesu ti Nasareti wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi.”

48 Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi ṣàánú fún mi.”

49 Nígbà tí Jesu gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹ́sẹ̀ dúró lójú ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.”

Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, “Tújúká! Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́.” 50 Lẹ́sẹ̀kan náà, Bartimeu bọ́ agbádá rẹ̀ sọnù, ó fò sókè, ó sì wá sọ́dọ̀ Jesu.

51 Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ?”

Afọ́jú náà dáhùn pé, “Rabbi, jẹ́ kí èmi kí ó ríran.”

52 (C)Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin afọ́jú náà ríran ó sì ń tẹ̀lé Jesu lọ ní ọ̀nà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.