Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 61

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
    Tẹ́tí sí àdúrà mi.

Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
    Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
    ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
    pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
    kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

2 Ọba 5:19-27

19 Eliṣa wí pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.”

Lẹ́yìn ìgbà tí Naamani tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà, 20 Gehasi, ìránṣẹ́ Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ́nú lórí Naamani, ará Aramu, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ní ọwọ́ rẹ̀.”

21 Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáradára?” ó béèrè.

22 “Gbogbo nǹkan wà dáradára,” Gehasi dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Efraimu. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

23 Naamani wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Gehasi láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Gehasi. 24 Nígbà tí Gehasi sì dé ibi ilé ìṣọ́, ó gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn, ó sì tó wọ́n sínú ilé, ó sì jọ̀wọ́ àwọn ọkùnrin náà lọ́wọ́ lọ, wọ́n sì jáde lọ. 25 Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa.

“Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè.

“Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn.

26 Ṣùgbọ́n Eliṣa wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà olifi, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin? 27 Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

Efesu 6:10-20

Ìhámọ́ra Ọlọ́run

10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14 (A)Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15 (B)Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìhìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

18 Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. 19 Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìhìnrere náà. 20 Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n: kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.