Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Ọba 5:1-3

Ìwòsàn Naamani adẹ́tẹ̀

Naamani jẹ́ olórí ogun ọba Aramu. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni Olúwa ti fi ìṣẹ́gun fún Aramu. Òun jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.

Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani. Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

2 Ọba 5:7-15

Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”

Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa. 10 Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”

11 Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn. 12 Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.

13 Ìránṣẹ́ Naamani lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòó mélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!” 14 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.

15 Nígbà náà Naamani àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsin yìí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Israẹli nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”

Saamu 111

111 Ẹ máa yin Olúwa.

Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
    ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
    àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
    Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
    òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
    láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
Wọ́n dúró láé àti láé,
    ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
    ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
    Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
    ìyìn rẹ̀ dúró láé.

2 Timotiu 2:8-15

Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 10 Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé.

11 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:

Bi àwa bá bá a kú,
    àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12 Bí àwa bá faradà,
    àwa ó sì bá a jẹ ọba:
Bí àwa bá sẹ́ ẹ,
    òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13 Bí àwa kò bá gbàgbọ́,
    òun dúró ni olóòtítọ́:
    Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.

Òṣìṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn

14 Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. 15 Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ

Luku 17:11-19

Ìwòsàn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá

11 (A)Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili. 12 (B)Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè: 13 (C)Wọ́n sì kígbe sókè, wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”

14 (D)Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.

15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. 16 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.

17 Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? 18 A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” 19 (E)Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.