Revised Common Lectionary (Complementary)
111 Ẹ máa yin Olúwa.
Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.
2 Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
3 Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
4 Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.
6 Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
8 Wọ́n dúró láé àti láé,
ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
9 Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.
10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
ìyìn rẹ̀ dúró láé.
Àbájáde kíka àwọn ọmọ Lefi
34 Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kohati nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
35 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ ìpàdé. 36 Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó-dínàádọ́ta (2,750). 37 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.
38 Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
39 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 40 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó-lé-ọgbọ̀n (2,630). 41 Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ Olúwa.
42 Wọ́n ka àwọn ọmọ Merari nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
43 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 44 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200). 45 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Merari. Mose àti Aaroni kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.
46 Gbogbo àwọn tí a kà nínú àwọn ọmọ Lefi, ti Mose àti Aaroni àti àwọn olórí Israẹli kà, nípa ìdílé wọn àti gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. 47 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn ẹrù inú Àgọ́ Ìpàdé. 48 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580). 49 Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Wíwà ní mímọ́ ibùdó
5 Olúwa sọ fún Mose pé: 2 (A)“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú. 3 Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn” 4 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.
2 Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu. 2 Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. 3 Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. 4 Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn. 5 Ní ọ̀nà kan náà, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń díje bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà 6 Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso. 7 Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.