Revised Common Lectionary (Complementary)
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
3 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
5 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi
ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú,
ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,
ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀
ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
7 Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
8 Nítorí ìwọ ti kó orílẹ̀-èdè púpọ̀,
àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀
Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
9 “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,
kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!
10 Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ
11 Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.
Ìgbàgbọ́ nínú ọmọ Ọlọ́run
5 (A)Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú. 2 Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. 3 (B)Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira, 4 (C)nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa. 5 Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?
Àwọn àfiyèsí ìparí
13 (A)Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. 14 (B)Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa; 15 Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
16 Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú: èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí. 17 Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀: ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.
18 (C)Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án. 19 Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà. 20 (D)Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.
21 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.