Revised Common Lectionary (Complementary)
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
3 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Ìdáhùn Olúwa
5 (A)“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,
Kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.
6 (B)Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,
àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn
tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já
láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.
7 Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,
ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,
Yóò máa ti inú wọn jáde.
8 Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,
wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ
àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;
wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun
9 Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá
ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;
wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.
10 Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín
wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.
Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín;
Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á
11 Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,
yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”
Ìráhùn lẹ́ẹ̀kejì Habakuku
12 Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?
Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú
Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;
Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí
13 Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;
ìwọ kò le gbà ìwà ìkà
nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?
Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa
ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?
14 Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,
bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso
15 Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè
ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;
nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
16 Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀
nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn
tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
17 Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,
tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
Àwọn ìṣòro àti àwọn ìdánwò
2 Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; 3 nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. 4 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun. 5 Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè. 7 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa; 8 Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìlèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.
9 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga. 10 (A)Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ. 11 Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.