Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
12 Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;
Olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
2 Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;
ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.
3 Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn
àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
4 tí ó wí pé,
“Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;
àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?”
5 “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,
Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni Olúwa wí.
“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”
6 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,
gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,
tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.
7 Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́
kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
8 Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri
nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,
ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.
13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;
ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.
14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,
ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.
15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.
16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.
17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,
a sì kórìíra eléte ènìyàn.
18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀
ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.
19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere
àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.
20 Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀
ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.
21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀
ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.
22 Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí?
Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.
23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá,
ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.
24 Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn
ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.
25 Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là
ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.
26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,
yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.
27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,
tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,
ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun.
29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,
ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,
ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn
ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
Peteru àti Johanu níwájú àwọn Sadusi
4 Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn Sadusi dìde sí wọn. 2 Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàásù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jesu. 3 Wọn sì nawọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ọjọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan. 4 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000).
5 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerusalẹmu. 6 Àti Annasi olórí àlùfáà, àti Kaiafa, àti Johanu, àti Aleksanderu, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà. 7 Wọ́n mú Peteru àti Johanu dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?”
8 Nígbà náà ni Peteru kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn! 9 Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá, 10 Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá. 11 (A)Èyí ni
“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’
12 Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.