Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 113

113 Ẹ máa yin Olúwa.

Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
    ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
    orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.

Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
    àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
    tí ó gbé ní ibi gíga.
Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
    òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!

Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé
    ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
    àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
    àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.

Ẹ yin Olúwa.

Eksodu 23:1-9

Òfin òdodo àti àánú

23 (A)“Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀: Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.

“Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣe aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn. (B)Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú sí tálákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.

“Bí ìwọ bá ṣe alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ tí ó ṣìnà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un. Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó kórìíra rẹ tí ẹrù ṣubú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀; rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ.

“Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo. (C)Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre.

(D)“Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́.

(E)“Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti.

Romu 3:1-8

Ìṣòtítọ́ Ọlọ́run

Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? (A)Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.

Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? (B)Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
    ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”

(C)Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn). Kí a má rí i. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé? Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀? (D)Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bi wọn tọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.