Revised Common Lectionary (Complementary)
Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.
127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.
3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
ojú kì yóò tì wọ́n,
ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.
16 Mo sì tún rí ohun mìíràn ní
abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,
òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀.
17 Mo wí nínú ọkàn mi,
“Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́
olódodo àti ènìyàn búburú,
nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,
àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.”
18 Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí. 19 Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn. 20 Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí. 21 Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ni?”
22 Nígbà náà, ni mo wá rí i wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ kò sí!
Ìnilára, làálàá, àti àìlọ́rẹ̀ẹ́
4 Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn,
mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò
sì ní olùtùnú kankan,
agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára,
wọn kò sì ní olùtùnú kankan.
2 Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú
tí wọ́n sì ti lọ,
ó sàn fún wọn ju àwọn
tí wọ́n sì wà láààyè lọ.
3 Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju
àwọn méjèèjì lọ:
ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú
tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.
4 Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
5 Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò
ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
6 Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà,
àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.
7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:
8 Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà;
kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí
kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo,
síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn,
bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá,
àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”
Eléyìí náà asán ni
iṣẹ́ òsì!
Àwọn ìlànà fún ìjọ
2 Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; 3 Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: 4 Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. 5 (A)Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. 6 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.