Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 138

Ti Dafidi

138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
    níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
    ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
    Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
    nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
    ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
    Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
    Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

Esteri 2:19-3:6

Mordekai Tú Àṣírí Ìṣọ̀tẹ̀

19 Nígbà tí àwọn wúńdíá tún péjọ ní ìgbà kejì, Mordekai jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. 20 Ṣùgbọ́n Esteri pa àṣírí ìdílé e rẹ̀ àti ibi tí ó ti wá mọ́ gẹ́gẹ́ bí Mordekai ṣe sọ fún un pé kí ó ṣe, nítorí tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ tí Mordekai fún un gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Mordekai.

21 Ní àsìkò tí Mordekai jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba, Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Ahaswerusi. 22 Ṣùgbọ́n Mordekai sì mọ̀ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ̀ fún ayaba Esteri, Esteri sì sọ fún ọba, wọ́n sì fi ọlá fún Mordekai. 23 Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀rọ̀ náà tí ó sì jásí òtítọ́, a sì so àwọn ìjòyè méjèèjì náà kọ́. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a kọ sínú ìwé ìtàn ní iwájú ọba.

Ọ̀tẹ̀ Hamani láti pa àwọn Júù run

Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ. Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hamani, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún un.

Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Mordekai pé, “Èéṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.” Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hamani nípa rẹ̀ láti wò ó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Mordekai ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.

Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú. Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Mordekai jẹ́, ó kẹ́gàn láti pa Mordekai nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hamani ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Mordekai run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ahaswerusi.

Ìṣe àwọn Aposteli 1:15-20

15 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà) 16 (A)ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu: 17 Nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń ṣe tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí.”

18 (Judasi fi èrè àìṣòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì ṣubú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde. 19 Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.)

20 (B)Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé,

“ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro,
    kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’

àti,

“ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.