Revised Common Lectionary (Complementary)
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,
dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?
Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,
nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
Ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ lọ
13 Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn: 14 Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i. 15 Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà. 16 Nítorí náà mo sọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.
17 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ
ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.
18 Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ,
ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.
Àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́
31 (A)“Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run. 32 Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́. 33 Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì.
34 (B)“Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. 35 Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. 36 Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’
37 “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu? 38 Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa? Tàbí tí o wà ní ìhòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́? 39 Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò?’
40 (C)“Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, ‘lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni.’
41 (D)“Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀. 42 Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu. 43 Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò.’
44 “Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’
45 “Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, Nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’
46 “Nígbà náà wọn yóò sì kọjá lọ sínú ìyà àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.