Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 130

Orin fún ìgòkè.

130 Láti inú ibú wá ni
    èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
Olúwa, gbóhùn mi,
    jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

(A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
    Olúwa, tá ni ìbá dúró.
Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
    kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.

Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
    àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
Ọkàn mi dúró de Olúwa,
    ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
    àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
    nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
    àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
    kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.

2 Kronika 30:13-27

13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní oṣù kejì. 14 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kidironi.

15 Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa. 16 Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi. 17 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi ṣe ń tọ́jú àti pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa. 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù, 19 tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́ 20 Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá.

21 Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.

22 Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.

23 Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́. 24 Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́. 25 Gbogbo ìjọ ènìyàn Juda pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Israẹli jáde wá, àti àwọn àjèjì tí ó ti ilẹ̀ Israẹli jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Juda yọ̀. 26 Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jerusalẹmu: nítorí láti ọjọ́ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli, irú èyí kò sí ní Jerusalẹmu. 27 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àní sí ọ̀run.

Marku 2:1-12

Jesu wo aláàrùn ẹ̀gbà sàn

Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jesu tún padà wọ Kapernaumu, òkìkí kàn pé ó ti wà nínú ilé. Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn. (A)Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé. Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé, “Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”

Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?’ 10 Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé, 11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé àkéte rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.” 12 (B)Lójúkan náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé àkéte rẹ̀. Ó sì jáde lọ lójú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.