Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 32

Ti Dafidi. Maskili.

32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
    tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
    àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

Nígbà tí mo dákẹ́,
    egungun mi di gbígbó dànù
    nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
    àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
    ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
    ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
    ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
    wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
    èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
    tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
    kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
    ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
    ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

2 Samuẹli 13:23-39

23 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu: Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. 24 Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”

25 Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.

26 Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”

Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” 27 Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.

28 Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” 29 Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.

30 Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” 31 Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.

32 Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. 33 Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.”

Absalomu sálọ sí Geṣuri

34 Absalomu sì sá.

Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”

35 Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”

36 Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.

37 Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́.

38 Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta. 39 Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.

Jakọbu 4:1-7

Ìyọ̀ǹda ara ẹni fún Ọlọ́run

Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrín yín? Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà ara yín bí? Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní: ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè. Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.

Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa? (A)Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé,

“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
    ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.”

Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.