Revised Common Lectionary (Complementary)
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
ìwọ sì ti wò mí sàn.
3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
Ẹ̀bẹ̀ ní ti Absalomu
12 Obìnrin náà sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi ọba.”
Òun si wí pé, “Máa wí.”
13 Obìnrin náà sì wí pé, “Nítorí kín ni ìwọ sì ṣe ro irú nǹkan yìí sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run? Nítorí pé ní sísọ nǹkan yìí ọba ní ẹ̀bi, nítorí pé ọba kò mú ìsáǹsá rẹ̀ bọ̀ wá ilé. 14 Nítorí pé àwa ó sá à kú, a ó sì dàbí omi tí a tú sílẹ̀ tí a kò sì lè ṣàjọ mọ́; nítorí bí Ọlọ́run kò ti gbà ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ti ṣe ọ̀nà kí a má bá a lé ìsáǹsá rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
15 “Ǹjẹ́ nítorí náà ni èmi sì ṣe wá sọ nǹkan yìí fún olúwa mi ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti dẹ́rùbà mí; ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ èmi ó sọ fún ọba; ó lè rí bẹ́ẹ̀ pé ọba yóò ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un. 16 Nítorí pé ọba ò gbọ́, láti gbà ìránṣẹ́bìnrin rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà tí ó ń fẹ́ gé èmi àti ọmọ mi pẹ̀lú kúrò nínú ilẹ̀ ìní Ọlọ́run.’
17 “Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú; nítorí bí angẹli Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú: Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’ ”
Dafidi mọ̀ pé Joabu ni ó ṣe èyí
18 Ọba sì dáhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, “Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́.”
Obìnrin náà wí pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba máa wí?”
19 Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?”
Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láààyè, olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti wí: nítorí pé Joabu ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu. 20 Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Joabu ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n angẹli Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.”
Absalomu padà wá sí ilé
21 Ọba sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Absalomu padà wá.”
22 Joabu sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Joabu sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.”
23 Joabu sì dìde, ó sì lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu wá sí Jerusalẹmu. 24 Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Absalomu sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.
26 Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.”
Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé: 2 “Agrippa ọba, inú èmi tìkára mi dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi kan mi, 3 pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrín àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fi sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.
4 “Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerusalẹmu. 5 Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi. 6 Nísinsin yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́. 7 Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn. 8 Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde?
9 (A)“Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti. 10 Èyí ni mo sì ṣe ni Jerusalẹmu. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i. 11 Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú Sinagọgu dé inú Sinagọgu, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.