Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 96:1-9

96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
    Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
    Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
    ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

1 Ọba 6:23-38

23 Ní inú ibi mímọ́ jùlọ ni ó fi igi olifi ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga. 24 Apá kérúbù kìn-ín-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì. 25 Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèjì jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà. 26 Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. 27 Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́ apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrín yàrá náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29 Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù sí i àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko. 30 Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.

31 Nítorí ojú ọ̀nà ibi mímọ́ jùlọ ni ó ṣe ìlẹ̀kùn igi olifi sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri. 32 Àti lára ìlẹ̀kùn igi olifi náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ. 33 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi olifi onígun mẹ́rin fún ìlẹ̀kùn ilé náà. 34 Ó sì tún fi igi firi ṣe ìlẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀. 35 Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.

36 Ó sì fi ẹsẹẹsẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹsẹ̀ kan ìtí kedari kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún.

37 Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sifi. 38 Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Bulu, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.

2 Kọrinti 5:11-17

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà tí a yà sọ́tọ̀

11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 (A)Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14 (B)Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 (C)Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.