Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:1-3

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Saamu 107:23-32

23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀
    ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24 Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa,
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú
25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́
    tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì
    tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:
    nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi
27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:
    ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
    ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́
    bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́;
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,
    ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún
    Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn
    kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.

Jobu 29:1-20

Jobu rántí ìbùkún rẹ̀ àtẹ̀yìnwá

29 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:

“Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá,
    bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́;
Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí,
    àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;
Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi,
    nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi
Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi,
    nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;
Nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi,
    àti tí apata ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.

“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè,
    nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,
Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi,
    wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn;
Àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ,
    wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu;
10 Àwọn ọlọ́lá dákẹ́,
    ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn.
11 Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi,
    àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi;
12 Nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́,
    àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un
13 Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi,
    èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.
14 Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ,
    ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.
15 Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀
    fún amúnkùn ún.
16 Mo ṣe baba fún tálákà, mo ṣe
    ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí.
17 Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ènìyàn búburú,
    mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.

18 “Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóò kú nínú ilé mi,
    èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí iyanrìn.
19 Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi,
    ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.
20 Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀
    mi, ọrun mi sì padà di tuntun ní ọwọ́ mi.’

Ìṣe àwọn Aposteli 20:1-16

Paulu kọjá ní Makedonia àti Giriki

20 Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí Makedonia. Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Giriki. Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ. Sopateru ará Berea ọmọ Pirusi sì bá a lọ dé Asia, àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti Sekundu, àti Gaiu ará Dabe, àti Timotiu; Tikiku àti Tirofimu ará Asia.

A jí Eutiku dìde nínú òkú ní Troasi

Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Troasi. Àwa sì ṣíkọ̀ láti Filipi lọ lẹ́yìn àjọ àìwúkàrà, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Troasi ni ọjọ́ méje.

Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́. Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú. 10 Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.” 11 Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. 12 Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ìdágbére Paulu sí àwọn Alàgbà Efesu

13 Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Asosi, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Paulu sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ. 14 Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Asosi, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Miletu. 15 Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu. 16 Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.