Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 70

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
    Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
    kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
    yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
    ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
    kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
    “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
    wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
    Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.

Amosi 4:6-13

“Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín,
    àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín,
    síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,”
    ni Olúwa wí.

“Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró
    nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta.
Mo rán òjò sí ibùgbé kan
    ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn.
Oko kan ní òjò;
    àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ.
Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi
    wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,”
    ni Olúwa wí.

“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín
    mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n.
Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”
    ni Olúwa wí.

10 “Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín
    bí mo ti ṣe sí Ejibiti.
Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín.
    Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn.
Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”
    ni Olúwa wí.

11 “Mo ti bì ṣubú nínú yín,
    bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú
ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”
    ni Olúwa wí.

12 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli,
    àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín,
    ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.”

13 Ẹni tí ó dá àwọn òkè
    tí ó dá afẹ́fẹ́
    tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn,
ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn
    tí ó sì tẹ ibi gíga ayé.
    Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Matiu 24:1-14

Àwọn ààmì òpin ayé

24 (A)Bí Jesu ti ń kúrò ni tẹmpili, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n fẹ́ fi ẹwà tẹmpili náà hàn án. (B)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a yóò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

(C)Bí ó ti jókòó ní orí òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ ààmì ìpadà wá rẹ, àti ti òpin ayé?”

Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀.

(D)“Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi. 10 Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú, 11 ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ. 12 Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù, 13 ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà. 14 A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.