Revised Common Lectionary (Complementary)
Ti Dafidi.
144 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,
ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,
àti ìka mi fún ìjà.
2 Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.
3 Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
4 Ènìyàn rí bí èmi;
ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.
5 Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
6 Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;
gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò nínú omi ńlá:
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
8 Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké
ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.
9 Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
olókùn mẹ́wàá èmi yóò
kọ orin sí ọ
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.
Lọ́wọ́ pípanirun. 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
tí ẹnu wọn kún fún èké,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13 Àká wa yóò kún
pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
kí ó má sí ìkọlù,
kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
Ìdáǹdè Israẹli
27 Ní ọjọ́ náà,
Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà
idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára
Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì,
Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì;
Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.
2 Ní ọjọ́ náà
“Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.
3 Èmi Olúwa ń bojútó o,
Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà.
Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru
kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.
4 Inú kò bí mi.
Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!
Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun;
Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.
5 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;
jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”
6 Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,
Israẹli yóò tanná yóò sì rudi
èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
17 (A)Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 18 (B)Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 20 (C)Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,” 21 (D)Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.