Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
31 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
gbà mí nínú òdodo rẹ.
2 Tẹ́ etí rẹ sí mi,
gbà mí kíákíá;
jẹ́ àpáta ààbò mi,
jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
3 Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
4 Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
5 Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.
19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
kúrò nínú ìjà ahọ́n.
21 Olùbùkún ni Olúwa,
nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
“A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
23 Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
Olúwa pa olódodo mọ́,
ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le
gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.
Ìdájọ́ tí yóò wá sórí Israẹli
6 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Wọ́n ta olódodo fún fàdákà
àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.
7 Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀
bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára
Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà
Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́
8 Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ
Lórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́ ẹ̀jẹ́
ní ilé òrìṣà wọn
wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.
9 “Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn
gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari.
Òun sì le koko bí igi óákù
mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá
àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.
10 Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún
láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.
11 “Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín
àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri
èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?”
ni Olúwa wí.
Ṣíṣe ìdájọ́ ẹnìkejì
7 (A)“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. 2 Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.
3 (B)“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. 5 Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.
6 “Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.