Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”
52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
ó dàbí abẹ mímú,
ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
láé àti láéláé.
9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,
níbo sì ni òye ń gbe?
13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;
omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”
15 A kò le è fi wúrà rà á,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
16 A kò le è fi wúrà ofiri,
tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e.
17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;
iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?
Tàbí níbo ni òye ń gbé?
21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,
ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
22 Ibi ìparun àti ikú wí pé,
àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀,
òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.
24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé,
ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
25 Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́,
ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi.
26 Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,
tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
27 Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde;
ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.
28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,
“Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,
àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”
Ọ̀nà tóóró àti ọnà gbòòrò
13 (A)“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. 14 Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.
Igi àti èso rẹ̀
15 (B)“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.