Proverbs Monthly
26 Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè
ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.
2 Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà
èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè
èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.
3 Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.
4 Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.
5 Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
6 Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá
ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.
7 Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro
ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.
8 Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa
ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.
9 Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí
ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.
10 Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan
ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
11 (A)Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
12 Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?
Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.
13 Ọ̀lẹ wí pé: “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà
kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
14 Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.
15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ,
ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
16 Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,
ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.
17 Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú
ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.
18 Bí i asínwín ti ń ju
ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni
19 ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ
tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”
20 Láìsí igi, iná yóò kú
láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.
21 Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,
bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.
22 Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè
wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
23 Ètè jíjóni, àti àyà búburú,
dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.
24 Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀
ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.
25 Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́
nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
26 Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn
ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.
27 Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.
Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
28 Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,
ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.
27 Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la
nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.
2 Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ
àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnrarẹ̀.
3 Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo
ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.
4 Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀
ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?
5 Ìbániwí gbangba sàn
ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.
6 Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,
ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.
7 Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó
ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8 Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀
ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.
9 Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn
bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.
10 Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,
má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ
ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.
11 Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi
nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.
12 Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.
13 Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì
fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.
14 Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀
a ó kà á sí bí èpè.
15 Àyà tí ó máa ń jà dàbí
ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
16 dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun
tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.
17 Bí irin tí ń pọ́n irin mú
bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.
18 Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀
ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.
19 Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.
20 Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí
bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.
21 Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà,
ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.
22 Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,
fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́
ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.
23 Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà
bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
24 Nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí
adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.
25 Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé
26 àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ,
àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.
27 Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́
láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ
àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.