Old/New Testament
Ìdájọ́ àti ìgbàlà
65 (A)“Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi;
Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi.
Sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi,
Ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’
2 Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi síta
sí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle,
tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára,
tí wọ́n sì gbára lé èrò ara wọn
3 àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbo
lójú ara mi gan an,
wọ́n ń rú ẹbọ nínú ọgbà
wọ́n sì ń sun tùràrí lórí i pẹpẹ bíríkì;
4 wọ́n ń jókòó láàrín ibojì
wọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀;
tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,
tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́;
5 tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi,
nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’
Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi
iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó.
6 “Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi:
Èmi kì yóò dákẹ́,
ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́;
Èmi yóò san án padà sí àyà wọn
7 àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,”
ni Olúwa wí.
“Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá
wọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré,
Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọn
ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.”
8 Báyìí ni Olúwa wí:
“Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà
tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘má ṣe bà á jẹ́,
nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi;
Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.
9 Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu,
àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì;
àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,
ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.
10 Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,
àti Àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,
fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.
11 “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀
tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi,
tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadi
tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán,
12 Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà,
àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;
nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.
Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀
Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú mi
ẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.”
13 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun;
ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin,
àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu,
ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin;
àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀,
ṣùgbọ́n a ó dójútì yin.
14 Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin
láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè
láti inú ìrora ọkàn yín
àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn.
15 Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀
fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún;
Olúwa Olódùmarè yóò sì pa yín,
ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun
yóò fún ní orúkọ mìíràn
16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà
yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́;
Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà
yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́.
Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé
yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi.
Àwọn ọrun tuntun àti ayé tuntun
17 “Kíyèsi i, Èmi yóò dá
àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun
A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,
tàbí kí wọn wá sí ọkàn.
18 Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé
nínú ohun tí èmi yóò dá,
nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú
àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.
19 Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu
n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;
ariwo ẹkún àti igbe
ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.
20 “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀
ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,
tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;
ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún
ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;
ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan
ni a ó pè ní ẹni ìfibú.
21 Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.
22 Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé,
tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ,
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,
bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;
àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́
wọn fún ìgbà pípẹ́.
23 Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán,
wọn kí yóò bímọ fún wàhálà;
nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún,
àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.
24 Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn;
nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.
25 (B)Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀,
kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù,
ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò.
Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”
ni Olúwa wí.
Ìdájọ́ àti ìrètí
66 (C)Báyìí ni Olúwa wí:
“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi,
Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?
Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?
2 Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”
ni Olúwa wí.
“Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:
ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,
tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.
3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ
ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan
àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ,
dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ
dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá,
ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí,
dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà.
Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n,
ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;
4 Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn
n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.
Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,
nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀.
Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi
wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”
5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,
Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín,
tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,
‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo,
kí a le rí ayọ̀ yín!’
Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.
6 (D)Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá,
gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá!
Ariwo tí Olúwa ní í ṣe
tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun
tí ó tọ́ sí wọn.
7 (E)“Kí ó tó lọ sí ìrọbí,
ó ti bímọ;
kí ó tó di pé ìrora dé bá a,
ó ti bí ọmọkùnrin.
8 Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan
tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?
Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí
bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.
9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí
kí èmi má sì mú ni bí?”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ
nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”
Ni Ọlọ́run yín wí.
10 “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;
ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn
nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára;
Ẹ̀yin yóò mu àmuyó
ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
12 Nítorí báyìí ni Olúwa wí:
“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò
àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;
ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀
a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú
a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn
ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;
ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
15 Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná
àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;
òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,
àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.
16 Nítorí pẹ̀lú iná àti idà
ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.
17 “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.
18 “Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.
19 “Èmi yóò sì gbé ààmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. 20 Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́. 21 Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni Olúwa wí.
22 (F)“Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe wà níwájú mi títí láé,” ni Olúwa wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé. 23 Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí. 24 (G)“Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”
Àwọn ẹ̀kọ́ lórí ìsìn
2 Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn. 2 Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́. 3 Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa; 4 Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́. 5 Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà. 6 Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ. 7 Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, aposteli òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.
8 Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn. 9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, 10 bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.
11 Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́. 12 Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́. 13 (A)Nítorí Adamu ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Efa. 14 (B)Adamu kọ́ ni a tànjẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀. 15 Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.