Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 14-16

14 Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jakọbu,

    yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i
    yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn.
Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn,
    wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n
    wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn.
Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè
    gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin
ní ilẹ̀ Olúwa.
    Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn
    wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.

Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé:

    Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!
    Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!
Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,
    ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀
    pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,
nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè
    pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,
    wọ́n bú sí orin.
Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn
    igi kedari ti Lebanoni
ń yọ̀ lórí rẹ wí pé,
    “Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,
    kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”

Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè
    láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀
ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ
    gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé
ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn
    gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Gbogbo wọn yóò dáhùn,
    wọn yóò wí fún ọ wí pé,
“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú
    ìwọ náà ti dàbí wa.”
11 Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,
    pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,
àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ
    àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12 Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,
    ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!
A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé
    Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!
13 Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,
    “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;
Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè
    ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,
Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ
    ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.
14 Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀;
    Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”
15 Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ
    lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.

16 Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,
    wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:
“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì
    tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
17 Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,
    tí ó sì pa ìlú ńláńlá rẹ̀ run
    tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?”

18 Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀
    ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì
    gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀,
àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,
    àwọn tí idà ti gún,
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.
    Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,
20 A kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,
    nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́
    o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.

Ìran àwọn ìkà
    ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.
21 Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ
    nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn,
    wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀
    kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn.

22 “Èmi yóò dìde sókè sí wọn,”
    ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà,
    àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”
    ni Olúwa wí.
23 Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí
    àti sí irà;
Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,
    ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Asiria

24 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,

    “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,
    àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.
25 Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi,
    ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.
    Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,
    ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.”

26 Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,
    èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè.
27 Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,
    ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?
    Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì àwọn Filistini

28 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú:

29 (A)Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,
    pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;
láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀
    yóò ti hù jáde,
    èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
30 Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,
    àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.
Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,
    yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

31 Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, Ìwọ ìlú!
    Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!
Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,
    kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.
32 Kí ni ìdáhùn tí a ó fún
    agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà?
Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀,
    àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí
    a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu

15 (B)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu:
A pa Ari run ní Moabu,
    òru kan ní a pa á run!
A pa Kiri run ní Moabu,
    òru kan ní a pa á run!
Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
    sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
    Gbogbo orí ni a fá
    gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
    ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
Wọ́n pohùnréré
    Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
Heṣboni àti Eleale ké sóde,
    ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
    tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
    àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
    Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
    Ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
    wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn
Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
    àwọn koríko sì ti gbẹ,
gbogbo ewéko ti tán
    ewé tútù kankan kò sí mọ́.
Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní
    tí wọ́n sì tò jọ
wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́
    odò Poplari.
Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé
    ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
    igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
    síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
    àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

16 Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn
    ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,
láti Sela, kọjá ní aginjù,
    lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.
Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ
    tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu
    ní àwọn ìwọdò Arnoni.

“Fún wa ní ìmọ̀ràn
    ṣe ìpinnu fún wa.
Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru,
    ní ọ̀sán gangan.
Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,
    má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han
Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,
    jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”

Aninilára yóò wá sí òpin,
    ìparun yóò dáwọ́ dúró;
    òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.
Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,
    ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀
ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.
    Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,
    yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.

Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,
    ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,
gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,
    wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.
Sọkún kí o sì banújẹ́
    fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.
Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,
    bákan náà ni àjàrà Sibma rí.
Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè
    wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,
èyí tí ó ti fà dé Jaseri
    ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.
Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,
    ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.
Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,
    fún àwọn àjàrà Sibma.
Ìwọ Heṣboni, Ìwọ Eleale,
    mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!
Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ
    àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.
10 Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò
    nínú ọgbà-igi eléso rẹ;
kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí
    kígbe nínú ọgbà àjàrà:
ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,
    nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.
11 Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,
    àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.
12 Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,
    ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;
Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà
    òfo ni ó jásí.

13 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu. 14 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé: “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”

Efesu 5:1-16

Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, (A)ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.

Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn.

Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀: (Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). 10 Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. 11 Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. 12 Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. 13 Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. 14 Nítorí náà ni ó ṣe wí pé,

“Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun,
    sí jíǹde kúrò nínú òkú
Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”

15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16 (B)Ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.