Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Orin Solomoni 1-3

Orin àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni.

Olólùfẹ́

Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,
    nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.
    Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde
    abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ.
Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá
    ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.

Ọ̀rẹ́

Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;
    a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.

Olólùfẹ́

Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!

Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
    Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
    dúdú bí àgọ́ Kedari,
    bí aṣọ títa ti Solomoni
Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
    nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
    ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
    ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.
Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,
    níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,
    kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán
ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

Ọ̀rẹ́

Bí ìwọ kò bá mọ̀,
    ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.
Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ,
    kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.
Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.

Olùfẹ́

Olùfẹ́ mi,
    mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao.
10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,
    ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀
11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,
    a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.

Olólùfẹ́

12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀,
    òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.
13 Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi,
    òun ó sinmi lé àárín ọmú mi.
14 Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi
    láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi.

Olólùfẹ́

15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!
    Háà, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!
    Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.

Olólùfẹ́

16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!
    Háà, Báwo ni o ṣe wu ni!
    Ibùsùn wa ní ìtura.

Olùfẹ́

17 Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari
    ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.

Olólùfẹ́

Èmi ni ìtànná Ṣaroni
    bí ìtànná lílì àwọn Àfonífojì.

Olólùfẹ́

Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún
    ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá.

Olólùfẹ́

Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó,
    ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,
    Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.
Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè,
    ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.
Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.
    Fi èso ápù tù mi lára
    nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
    mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú
kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè
    kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.

Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!
    Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.
Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,
    Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèkéé
Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín
    Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa
Ó yọjú ní ojú fèrèsé
    Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà
10 Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,
    “Dìde, Olólùfẹ́ mi,
    arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;
    òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀
    àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé
    a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13 Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,
    àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn,
Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi;
    Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”

Olùfẹ́

14 Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,
    ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,
fi ojú rẹ hàn mí,
    jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;
Nítorí tí ohùn rẹ dùn,
    tí ojú rẹ sì ní ẹwà.
15 Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,
    àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèkéé
tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,
    àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.

Olólùfẹ́

16 Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀;
    Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì.
17 Títí ìgbà ìtura ọjọ́
    títí òjìji yóò fi fò lọ,
yípadà, olùfẹ́ mi,
    kí o sì dàbí abo egbin
tàbí ọmọ àgbọ̀nrín
    lórí òkè Beteri.

Ní orí ibùsùn mi ní òru
    mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;
    mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,
    ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;
Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
    Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
    bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.
    “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”
Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀
    ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ
    títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,
    sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
    Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú
kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè
    kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.

Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá
    bí ọ̀wọ̀n èéfín
tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára
    pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?
Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,
    àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,
    àwọn akọni Israẹli,
Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,
    gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,
idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,
    wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru
Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;
    o fi igi Lebanoni ṣe é.
10 Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀
    o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀
Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,
    inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí
    “Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
11 Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,
    kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,
    adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e
ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,
    ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Galatia 2

Àwọn aposteli tẹ́wọ́ gba Paulu

(A)Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìhìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. (B)Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìhìnrere náà.

(C)Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìhìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìhìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà. Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. 10 Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.

Paulu tako Peteru

11 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. 12 Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. 13 Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà.

14 Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù?

15 “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’ 16 (E)Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! 18 Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin.

19 “Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run. 20 (F)A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi. 21 Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan: nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.