Old/New Testament
Besaleli àti Oholiabu
31 (A)Olúwa wí fún Mose pé, 2 “Wò ó, èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 3 Èmi sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 4 Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, 5 láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 6 Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́.
“Bákan náà, èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ:
7 “àgọ́ àjọ náà,
àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀,
àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,
8 tábìlì àti ohun èlò rẹ̀,
ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,
pẹpẹ tùràrí,
9 pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,
agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀,
10 àti aṣọ híhun pẹ̀lú,
papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà
àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,
11 òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́.
“Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”
Ọjọ́ ìsinmi
12 (B)Olúwa wí fún Mose pé, 13 “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.
14 “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ. 15 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́. 16 Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé. 17 Yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”
18 Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.
Ère òrìṣà wúrà
32 (C)Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”
2 Aaroni dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.” 3 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Aaroni. 4 Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.”
5 Nígbà ti Aaroni rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí Olúwa.” 6 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.
7 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Ejibiti, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀. 8 Wọ́n ti yí kánkán kúrò nípa ọ̀nà tí mo ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹgbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rú ẹbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Israẹli wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.’ ”
9 (E)Olúwa wí fún Mose pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn. 10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbóná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.”
11 Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára? 12 Èéṣe tí àwọn ará Ejibiti yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́n mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ. 13 Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnrarẹ̀: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ” 14 Nígbà náà ni Olúwa dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.
15 Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin. 16 Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín in sára àwọn òkúta wàláà náà.
17 Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”
18 Mose dáhùn pé:
“Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun,
kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun;
ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.”
19 Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà. 20 Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún.
21 Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”
22 Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó. 23 (F)Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’ 24 Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”
25 Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. 26 Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká.
27 Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wí pé: ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládùúgbò rẹ.’ ” 28 Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ènìyàn. 29 Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.”
30 Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”
31 Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. 32 (G)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”
33 Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. 34 Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
35 Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.
33 Olúwa sọ fún Mose pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Ejibiti wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí èmi ti pinnu ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ 2 Èmi yóò rán angẹli ṣáájú yín, èmi yóò sì lé àwọn Kenaani, àwọn ará Amori, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde. 3 (H)Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”
4 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀. 5 Nítorí Olúwa ti wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wá sí àárín yín ni ìṣẹ́jú kan, èmi lè pa yín run. Ní ṣinṣin yìí, bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò ṣe pẹ̀lú rẹ.’ ” 6 Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Horebu.
Àgọ́ àjọ
7 Mose máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń béèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó. 8 Nígbàkúgbà tí Mose bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mose títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà. 9 Bí Mose ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mose. 10 Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. 11 (I)Olúwa máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ lójúkojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mose yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Joṣua ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Nuni kò fi àgọ́ sílẹ̀.
Mose àti ògo Olúwa
12 Mose sọ fún Olúwa pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́n nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojúrere mi pẹ̀lú.’ 13 Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́n, kí n sì le máa wá ojúrere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀-èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”
14 Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”
15 Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. 16 Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”
17 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.”
18 Mose sì wí pé “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.”
19 (J)Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún. 20 Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ènìyàn kan tí ń rí mi, tí ó lè yè.”
21 Olúwa sì wí pé, “Ibìkan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta. 22 Nígbà tí ògo mi bá kọjá, èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí èmi yóò fi rékọjá. 23 Nígbà tí èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi; ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí.”
Òwe àsè ìgbéyàwó
22 (A)Jesu tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé: 2 “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àsè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 3 Ó rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ pe àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ sí ibi àsè ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá.
4 “Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti ṣe àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyàwó.’
5 “Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kà á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.” 6 Àwọn ìyókù sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àbùkù sí wọn, wọ́n lù wọ́n pa. 7 Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn.
8 “Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà. 9 Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà.’ 10 Nítorí náà, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà. Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àsè ìyàwó sì kún fún àlejò.
11 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. 12 Ọba sì bi í pé, ‘Ọ̀rẹ́, báwo ni ìwọ ṣe wà níhìn-ín yìí láìní aṣọ ìgbéyàwó?’ Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kò ní ìdáhùn kankan.
13 (B)“Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wà.’
14 “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”
Sísan owó orí fún Kesari
15 (C)(D) Nígbà náà ni àwọn Farisi péjọpọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un. 16 Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olóòtítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 17 Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?”
18 Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò? 19 Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un, 20 ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?”
21 (E)Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.”
“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.