Old/New Testament
Ìdájọ́ fún ẹsẹ̀ Israẹli
9 Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli;
má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín.
Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè
ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.
2 Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ
wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀
3 Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa
Efraimu yóò padà sí Ejibiti
Yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.
4 Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.
Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.
Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.
Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.
Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnrawọn
kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.
5 Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn
ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?
6 Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun
Ejibiti yóò kó wọn jọ,
Memfisi yóò sì sin wọ́n.
Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún,
Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.
Ẹ̀gún yóò sì bo
gbogbo àgọ́ wọn.
7 (A)Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;
àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé
Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí
Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀
ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.
A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀
A ka ẹni ìmísí sí asínwín.
8 Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,
ni olùṣọ́ ọ Efraimu.
Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀
9 Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́
gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah
Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
10 “Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù.
Mo rí àwọn baba yín,
bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀.
Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ,
wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni,
ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. 11 Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ
kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.
12 Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà.
Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn
Ègbé ni fún wọn,
nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!
13 Mo rí Efraimu bí ìlú Tire
tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára
ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn
ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”
14 Fún wọn, Olúwa!
Kí ni ìwọ yóò fún wọn?
Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́
àti ọyàn gbígbẹ.
15 “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali
Mo kórìíra wọn níbẹ̀,
nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi
Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́
ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.
16 Efraimu ti rẹ̀ dànù
gbogbo rẹ̀ sì ti rọ,
kò sì so èso,
Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.
Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”
17 Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀
nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i;
wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀
ó ń so èso fún ara rẹ̀
Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i
bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere
o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.
2 Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ
báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn.
Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀
yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.
3 Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba
nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa
ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba,
kí ni yóò ṣe fún wa?”
4 Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀,
wọ́n ṣe ìbúra èké,
wọ́n da májẹ̀mú;
báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko,
bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro.
5 Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù
nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni
Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀
Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀,
nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.
6 A ó gbé lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá
a ó dójútì Efraimu;
ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀
7 Bí igi tó léfòó lórí omi ni
Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.
8 (B)Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun—
èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli.
Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde,
yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn.
Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!”
àti fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Ṣubú lù wá!”
9 “Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli
ìwọ sì tún wà níbẹ̀.
Ǹjẹ́ ogun kò lé
ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí?
10 Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n;
orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ wọ́n ó sì dojúkọ wọn
Láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
11 Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́,
to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà;
lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni
èmi ó dí ẹrù wúwo lé.
Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin
Juda yóò tú ilẹ̀,
Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀.
12 (C)Ẹ gbin òdòdó fún ara yín,
kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin,
Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro,
nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa,
títí tí yóò fi dé,
tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.
13 Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi,
Ẹ ti jẹ èso èké
nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín
àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín
14 Ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín
kí gbogbo odi agbára yín ba le parun.
Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun,
nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn
15 Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli,
nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù.
Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà,
a o pa ọba Israẹli run pátápátá.
Ìfẹ́ Ọlọ́run sí Israẹli
11 (D)“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀,
mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.
2 Bí a ti ń pe wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi,
wọn rú ẹbọ sí Baali,
wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.
3 Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn
mo di wọ́n mú ní apá,
ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀
pé mo ti mú wọn láradá.
4 Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n
àti ìdè ìfẹ́.
Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn
Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.
5 “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí
Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí
nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?
6 Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn
yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́
yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn.
7 Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi
bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ,
kò ní gbé wọn ga rárá.
8 “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu?
Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma?
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣeboimu?
Ọkàn mi yípadà nínú mi
àánú mi sì ru sókè
9 Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ,
tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro.
Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn
Ẹni mímọ́ láàrín yín,
Èmi kò ní í wá nínú ìbínú
10 Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;
òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún
Nígbà tó bá bú
àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.
11 Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù
bí i ẹyẹ láti Ejibiti
bí i àdàbà láti Asiria
Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,”
ni Olúwa wí.
Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli
12 Efraimu tí fi irọ́ yí mi ká
ilé Israẹli pẹ̀lú ẹ̀tàn.
Ṣùgbọ́n Juda sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run
Ó sì ṣe olóòtítọ́ sí Ẹni mímọ́ Israẹli.
Sí ìjọ ní Sardi
3 “Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé:
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé:
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú. 2 Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tàbí tí ó ṣetán láti kú: Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run. 3 Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.
4 Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sardi, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ. 5 (A)Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀. 6 Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
Sí ìjọ Filadelfia
7 (B)“Àti sí angẹli Ìjọ ni Filadelfia kọ̀wé:
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòtítọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dafidi, ẹni tí ó ṣí, tí kò sí ẹni tí yóò tì; ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i:
8 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀: kíyèsi i, mo gbe ìlẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í; pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi. 9 (C)Kíyèsi i, èmi ó mú àwọn ti Sinagọgu Satani, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsi i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ. 10 Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.
11 Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán: di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ. 12 (D)Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́: èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi. 13 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
Sí ìjọ Laodikea
14 (E)“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé:
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run:
15 Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná. 16 Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. 17 (F)Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: 18 Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.
19 (G)Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà: nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà. 20 Kíyèsi i, èmi dúró ni ẹnu ìlẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohun mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.
21 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.