Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 34-36

Ìdájọ́ Ọlọ́run lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè

34 (A)Súnmọ́ tòsí,
    ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́,
tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn
    jẹ́ kí ayé gbọ́,
àti ẹ̀kún rẹ̀,
    ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde.
Nítorí ìbínú Olúwa ń bẹ
    lára gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ìrunú rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn:
    o ti fi wọ́n fún pípa,
Àwọn ti a pa nínú wọn
    ni a ó sì jù sóde,
òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde,
    àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn
(B)Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́,
    a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá,
gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀,
    bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà,
    àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run,
    kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu,
    sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́.
Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀
    a mú un sanra fún ọ̀rá,
àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
    fún ọ̀rá ìwé àgbò—
nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bosra,
    àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu.
Àti àwọn àgbáǹréré yóò
    ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá,
àti àwọn ẹgbọrọ màlúù
    pẹ̀lú àwọn akọ màlúù,
ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,
    a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá.

Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni,
    àti ọdún ìsanpadà,
    nítorí ọ̀ràn Sioni.
(C)Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà,
    àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́,
    ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná.
10 A kì yóò pa á ní òru tàbí ní ọ̀sán,
    èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé:
yóò dahoro láti ìran dé ìran,
    kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé
àti láéláé.
11 Òwìwí aginjù, àti àkàlà ni yóò ni ín,
    àti òwìwí àti ẹyẹ ìwò ni yóò máa gbé inú rẹ̀.
Ọlọ́run yóò sì na sórí Edomu
    okùn ìwọ̀n ìparun
    àti òkúta òfo.
12 Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀
    ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀
tiwọn ó pè wá sí ìjọba,
    gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán.
13 Ẹ̀gún yóò sì hù jáde
    nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí,
ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀.
    Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá
    àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.
14 Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé,
àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀,
    iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú,
    yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀.
15 Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbẹ̀,
    yóò yé, yóò sì pa,
yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀:
    àwọn gúnnugún yóò péjọ síbẹ̀ pẹ̀lú,
    olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.

16 Ẹ wá a nínú ìwé Olúwa, ẹ sì kà á:

Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí kì yóò yẹ̀,
    kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ èkejì rẹ̀ kù:
nítorí Olúwa ti pàṣẹ
    ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ
    Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.
17 Ó ti di ìbò fún wọn,
    ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn
nípa títa okùn,
    wọn ó jogún rẹ̀ láéláé,
láti ìran dé ìran
    ni wọn ó máa gbé inú rẹ̀.

Ayọ̀ àwọn ẹni ìràpadà

35 Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn;
    aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.
    Gẹ́gẹ́ bí ewéko,
Ní títanná yóò tanná;
    yóò yọ ayọ̀ ńláńlá yóò sì kọrin.
Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un,
    ẹwà Karmeli àti Ṣaroni;
wọn yóò rí ògo Olúwa,
    àti ẹwà Ọlọ́run wa.

(D)Fún ọwọ́ àìlera lókun,
    mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:
Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé
    “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
    òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
    òun yóò wá láti gbà yín là.”

(E)Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú
    àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,
    àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.
Odò yóò tú jáde nínú aginjù
    àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
    ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
Ní ibùgbé àwọn dragoni,
    níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
    ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.

Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:
    a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́.
Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;
    yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,
    àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.
Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,
    tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀;
a kì yóò rí wọn níbẹ̀.
    Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
10 àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
    Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin;
ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.
    Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,
    ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Sennakeribu dẹ́rùba Jerusalẹmu

36 (F)Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Hesekiah, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda ó sì kó gbogbo wọn. Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá Alágbàfọ̀, Ṣebna Eliakimu ọmọ Hilkiah alábojútó ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.

Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Hesekiah,

“ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ pé: Lórí i kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé? Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ asán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi? Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e. Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”?

“ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria: Èmi yóò fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí! Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kan ṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn balógun olúwa mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti fún kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin? 10 Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀-èdè yìí jà kí n sì pa á run.’ ”

11 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu, Ṣebna àti Joah sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”

12 Ṣùgbọ́n ọ̀gágun náà dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò wí pé ọ̀gá yín àti ẹ̀yin nìkan ni ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ni, tí kì í sì ṣe sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó jókòó lórí ògiri, àwọn tí ó jẹ́ pé wọn yóò jẹ ìgbẹ́ wọn tí wọ́n yóò sì mu ìtọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà?”

13 Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria! 14 Ohun tí ọba wí nìyìí: Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! 15 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.’

16 “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí: Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀, 17 títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.

18 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí? 19 Níbo ni àwọn òrìṣà Hamati àti Arpadi ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Sefarfaimi ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Samaria gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí? 20 Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?”

21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.”

22 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu ọmọ Hilkiah alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.

Kolose 2

Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodikea àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí. Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀. (A)Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìṣúra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí. Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma ba à fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín ṣìnà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsi ètò yín àti bí ìdúró ṣinṣin yín nínú Kristi ti rí.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú ẹ̀mí nínú Kristi

Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.

Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.

Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, 10 (B)ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. 11 Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. 12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.

13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; 14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. 15 (C)Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn.

16 (D)Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: 17 (E)Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ní inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn angẹli lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nípa èrò ti ọkàn ara rẹ̀. 19 (F)Wọn ti sọ ìdàpọ̀ wọn pẹ̀lú ẹni tí i ṣe orí nu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.

20 (G)Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kristi si àwọn agbára ìlànà ayé yìí, kín ló dé tí ẹ̀yin ń tẹríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé, 21 Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fi ọwọ́ bà á, 22 (H)Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn? 23 Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, nípasẹ̀ àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọ́nra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè láti di ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ku.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.