Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 60-62

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀.

60 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
    Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
    mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
    Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
    kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

(A)Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
    kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
    “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
    èmi ó sì wọ́n Àfonífojì Sukkoti.
Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
    Efraimu ni àṣíborí mi,
    Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
    lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
    Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
    tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
    nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
    yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
    Tẹ́tí sí àdúrà mi.

Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
    Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
    ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
    pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
    kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.

62 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;
    ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?
    Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,
    bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú
    kúrò nínú ọlá rẹ̀;
    inú wọn dùn sí irọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
    ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.

Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.
    Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;
    Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;
    tú ọkàn rẹ jáde sí i,
nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké
    sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,
    lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,
    tàbí gbéraga nínú olè jíjà,
nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
    má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.

11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo
    gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ni agbára
12 (B)Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú
    nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

Romu 5

Àlàáfíà àti ayọ̀

(A)Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. (B)Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. (C)Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: (D)Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. (E)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

(F)Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (G)Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 (H)Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.

Ikú nípasẹ̀ Adamu, iyè nípasẹ̀ Jesu

12 (I)Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀:

13 Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí. 14 (J)Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.

15 (K)Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí o bá jẹ pé ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn nínú oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jesu Kristi, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀. 16 (L)Kì í ṣe nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà: Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre, 17 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jẹ ọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jẹ ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jesu Kristi.

18 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. 19 (M)Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.

20 (N)Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá. 21 (O)Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jẹ ọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.