Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Read the New Testament in 24 Weeks

A reading plan that walks through the entire New Testament in 24 weeks of daily readings.
Duration: 168 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Ìfihàn 7-8

Ọ̀kẹ́ méje-olé-ẹgbàá-méjì èdìdì ìwé

(A)Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi. Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, (B)wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si: Àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.

Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Aṣeri a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Naftali a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Manase a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú ẹ̀wù funfun

Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn. 10 Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:

“Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá
tí o jókòó lórí ìtẹ́,
àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”

11 Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12 Wí pe:

“Àmín!
Ìbùkún, àti ògo,
àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,
àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!
Àmín!”

13 Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”

14 (C)Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”

Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 15 Nítorí náà ni,

“wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run,
    tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀;
ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn.
16 (D)Ebi kì yóò pa wọn mọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́;
bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn
    tàbí oorukóoru kan.
17 (E)Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn,
    ‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè:’
‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”

Èdìdì keje àti àwo tùràrí

Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan.

Mo sì rí àwọn angẹli méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.

(F)Angẹli mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fi kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́. Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ sì gòkè lọ síwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ angẹli náà wá. (G)Angẹli náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé: A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.

Àwọn ìpè

Àwọn angẹli méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.

(H)Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀: Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ́ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ́ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jóná.

(I)Angẹli kejì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òkè-ńlá tí ń jóná, sínú Òkun: ìdámẹ́ta Òkun si di ẹ̀jẹ̀; àti ìdámẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú Òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.

10 (J)Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi; 11 A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.

12 Angẹli kẹrin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ́ta oòrùn, àti ìdámẹ́ta òṣùpá, àti ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ́ta wọn lè ṣókùnkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta rẹ̀, àti òru bákan náà.

13 Mo sì wò, mo sì gbọ́ idì kan tí ń fò ni àárín ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn angẹli mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.