Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Read the New Testament in 24 Weeks

A reading plan that walks through the entire New Testament in 24 weeks of daily readings.
Duration: 168 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Heberu 3-5

Jesu pọ̀ ju Mose lọ

Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu; (A)Ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run. Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ. Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. (B)Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

Ìkìlọ̀ fún aláìgbàgbọ́

(C)Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí:

“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
    Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,
    bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù:
Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,
    tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.
10 Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,
    mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn;
    wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
    ‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”

12 Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13 Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14 Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin; 15 (D)Nígbà tí a ń wí pé:

“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
    ẹ má sé ọkàn yin le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”

16 (E)Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose? 17 (F)Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù? 18 Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn? 19 Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.

Ìsinmi fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run

Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ba à dàbí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀. Nítorí tí àwa gbọ́ ìwàásù ìhìnrere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní àǹfààní, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ. (G)Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí,

“Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
    ‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé. (H)Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ keje báyìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.” (I)Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”

Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a ti wàásù ìhìnrere náà fún ní ìṣáájú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn: (J)Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú,

“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
    ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”

Nítorí, ìbá ṣe pé Joṣua tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ́yìn náà, nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. 10 (K)Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀. 11 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà.

12 Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú méjì lọ, ó sì ń gún ni, àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí ní yà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn. 13 Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.

Jesu ni olórí àlùfáà tòótọ́

14 Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jesu ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin. 15 Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀. 16 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.

Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó lè ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn aláìmòye, tí ó sì lé bá àwọn tí ó ti yapa kẹ́dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú. Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń ṣe fún ara rẹ̀ náà. Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni.

(L)Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú kò sì ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé,

“Ìwọ ni ọmọ mi,
    lónìí ni mo bí ọ.”

(M)Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé,

“Ìwọ ni àlùfáà títí láé
    ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

(N)Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀. Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀; (O)Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ tirẹ̀: 10 (P)Tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.

Ìkìlọ̀ lórí ṣíṣubú kúrò nínú ìgbàgbọ́

11 Nípa èyí àwa ní ohun púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti túmọ̀, nítorí pé ẹ yigbì ní gbígbọ́. 12 Nítorí pé báyìí ó ti yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ni, ẹ tún wà ní ẹni tí ẹnìkan yóò máa kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ sì tún di irú àwọn tí ó mu wàrà, tí wọn kò sì fẹ́ oúnjẹ líle. 13 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń mu wàrà jẹ́ aláìlóye ọ̀rọ̀ òdodo: nítorí ọmọ ọwọ́ ni. 14 Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle wà fún àwọn tí ó dàgbà, àwọn ẹni nípa ìrírí, tí wọn ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàrín rere àti búburú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.