Read the New Testament in 24 Weeks
Ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000)
14 (A)Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. 2 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù. 3 Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nnì àti àwọn àgbà náà: kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá. 4 Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà. 5 A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.
Àwọn angẹli mẹ́ta
6 Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. 7 Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”
8 (B)Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”
9 Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba ààmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. 10 (C)Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn: 11 (D)Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba ààmì orúkọ rẹ̀.” 12 Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.
13 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”
Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”
Ìkórè ayé
14 (E)Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o “dàbí Ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀. 15 (F)Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.” 16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.
17 Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan. 18 Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.” 19 Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run. 20 (G)A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.
Angẹli méje pẹ̀lú ìyọnu méje
15 (H)Mo sì rí ààmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn angẹli méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹyìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin. 2 Mo sì rí bí ẹni pé, Òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí Òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n ṣẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti ààmì rẹ̀ àti nọ́mbà orúkọ rẹ̀, wọn ní ohun èlò orin Ọlọ́run. 3 (I)Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:
“Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,
Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;
òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,
ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.
4 (J)Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,
tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?
Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,
ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,
nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”
5 (K)Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀; 6 àwọn angẹli méje náà sì ti inú tẹmpili jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dìwọ́n ni oókan àyà. 7 Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 8 Tẹmpili náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹmpili náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn angẹli méje náà ṣẹ.
Àwọn ago ìbínú Ọlọ́run
16 (L)Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹmpili wá, ń wí fún àwọn angẹli, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ago ìbínú Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì sí orí ayé.”
2 (M)Èkínní sì lọ, ó sì tú ago tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní ààmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀.
3 (N)Èkejì sì tú ago sínú Òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn: gbogbo ọkàn alààyè sì kú nínú Òkun.
4 Ẹ̀kẹta sì tú ago tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀. 5 Mo sì gbọ́ angẹli ti omi wí pé:
“Olódodo ni ìwọ Ẹni Mímọ́ ẹni tí ó ń bẹ,
tí ó sì ti wà,
nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ báyìí.
6 (O)Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀,
ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”
7 (P)Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé:
“Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,
òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”
8 Ẹ̀kẹrin sì tú ago tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára. 9 A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.
10 (Q)Ẹ̀karùnún sì tú ago tirẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora. 11 Wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.
12 (R)Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Eufurate; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèsè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà-oòrùn wá. 13 (S)Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dragoni náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá. 14 Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.
15 (T)“Kíyèsi i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń ṣọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó má bá a rìn ni ìhòhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”
16 (U)Ó sì gbá wọn jọ́ sí ibìkan tí a ń pè ní Amagedoni ní èdè Heberu.
17 (V)Èkeje si tú ago tirẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹmpili jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!” 18 (W)Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò ṣẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀. 19 Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un. 20 Olúkúlùkù erékùṣù sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́. 21 (X)Yìnyín ńlá, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó tálẹ́ǹtì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà: Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.