Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Read the New Testament in 24 Weeks

A reading plan that walks through the entire New Testament in 24 weeks of daily readings.
Duration: 168 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Timotiu 1-2

Ọ̀rọ̀ ìkíni

Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu.

Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n:

Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú láti jẹ́ onígbàgbọ́

Mo dá ọpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsimi lọ́sàn án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi. Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀. (A)Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú.

Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi. Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro. Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìhìnrere nípa agbára Ọlọ́run, ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé, 10 ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìhìnrere. 11 Fún ti ìhìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́. 12 Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí: nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.

13 Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu. 14 Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.

15 Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Asia ti fi mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Figeliu àti Hamogene gbé wà.

16 Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú. 17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Romu, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkára rẹ sá à mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà ràn mí lọ́wọ́ ni Efesu.

Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu. Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn. Ní ọ̀nà kan náà, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń díje bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso. Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.

Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 10 Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé.

11 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:

Bi àwa bá bá a kú,
    àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12 Bí àwa bá faradà,
    àwa ó sì bá a jẹ ọba:
Bí àwa bá sẹ́ ẹ,
    òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13 Bí àwa kò bá gbàgbọ́,
    òun dúró ni olóòtítọ́:
    Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.

Òṣìṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn

14 Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. 15 Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ 16 Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí tiwọn máa síwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run. 17 Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Filetu wà; 18 àwọn ẹni tí ó ti ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú. 19 (B)Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúrò nínú àìṣòdodo.”

20 Ṣùgbọ́n nínú ilé ńlá, kì í ṣe kìkì ohun èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá. 21 Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.

22 Máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èwe: sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá. 23 Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní ẹ̀kọ́ nínú ni kí o kọ̀, bí o ti mọ̀ pe wọn máa dá ìjà sílẹ̀. 24 Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù. 25 Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́, 26 wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdẹ̀kùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.